ONIBU ORE
Verse 1
Oluwa orun on aye
Wo Niyin atope ye fun
Bawo la ba ti fe o to
Onibu ore
Verse 2
Orun ti nran atefefe
Gbogbo eweko nso fe re
Wo lo nmu irugbin dara
Onibu ore
Verse 3
Fun ara lile wa gbogbo
fun gbogbo ibukun aye
Awa yin o, a si dupe
a onibu ore
Verse 4
O ko du wa li omo re
o fi fun aye ese wa
o si f’ebun gbogbo pelu
onibu ore
Verse 5
O fun wa l’Eni Mimo re
Emi iye atagbara
O rojo ekun ibukun re
Le wa lori
Verse 6
Fun idariji ese wa,
ati fun ireti orun
Ki lohun ta fin fun o
O je isura ti taye
Onibu ore
Verse 7
Owo ti anna, ofo ni
Sugbon eyi tafin fun o
O je isura ti taye
Onibu ore
Verse 8
Ohun ta bun o Oluwa
Wo o an le pada fun wa
Layo la ta o lore
Onibu ore
Verse 9
Ni odo re lati san wa
olorun olodumare
Je ka le ba O gbe titi
Onibu ore